Kekere
Bi o ṣe le lo ẹrọ yii
Nnkan ti o le ṣe
O le lo ẹrọ yii ti iwọ tabi eeyan to fẹ lo fun ba jẹ ;
- Ọmọ ọdun 18 tabi ju bẹ lọ
- Ti iru eeyan bẹ ba ti ṣe ayẹwo ifunpa, to si ti lo oogun tabi lo ẹrọ ifunpa nile
Nnkan ti o ko le ṣe
O ko le lo ẹrọ yii ti ìwọ ati eeyan to ba fẹ lo fun ba jẹ
- Ọmọ ọdun 17 tabi kere ju bẹẹ lọ
- Ti o ba loyun
- Ti o ba n lo oogun to le ṣe akoba fun ifunpa rẹ
- To ba ti ṣe iṣẹ abẹ tabi farapa
- Ti o ba n ṣe aisan to ni apẹẹrẹ oyi, èébì tabi ori fifọ
- To ba ṣẹsẹ ri onimọ lori ifunpa rẹ, ti wọn si fun ni imọran
- O ko gbọdọ lo ẹrọ yii lati ṣe ifidimulẹ apẹẹrẹ kankan. Lọ rí dokita rẹ, ti ọkan rẹ ko ba balẹ lori ifunpa rẹ.
Wo ọna to fi le ṣe ayẹwo ifunpa rẹ bo ṣe yẹ
Ti o ba n ṣe ayẹwo ifunpa rẹ ni ile, o ni awọn nnkan to le ṣe iranlọwọ fun ọ lati ṣe daadaa
- Joko lori aga to ni ifẹhinti
- Fi ẹsẹ rẹ lelẹ
- Gbe ọwọ sori tabili, ki o si ma mi apa rẹ, jẹ ko le lẹ
- Wọ aṣọ alapa kekere
- Fi ara balẹ, mi daadaa, ko si ma sọrọ lasiko ayẹwo
- Ṣe ayẹwo mii lẹyin isẹju diẹ ti o ṣe ti akọkọ lati ri pe o ba ara wọn mu
- Ṣe ayẹwo yii ni owurọ ati asalẹ.

























